1 Kings 13:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wolii àgbàlagbà náà gbọ́, ó ní, “Wolii tí ó ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ OLUWA ni. Nítorí náà ni OLUWA fi rán kinniun sí i, pé kí ó pa á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti kìlọ̀ fún un tẹ́lẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati woli ti o mu u lati ọ̀na pada bọ̀ gbọ́, o wipe, Enia Ọlọrun na ni, ti o ṣọ̀tẹ si Oluwa: nitorina li Oluwa fi i le kiniun lọwọ, ti o si fà a ya, ti o si pa a, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ OLÚWA jẹ́. OLÚWA sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti kìlọ̀ fún un.”