1 Kings 13:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Jeroboamu, ọba Israẹli kò yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀. Ṣugbọn ó ń yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù ú láàrin àwọn eniyan ó sì ń fi wọ́n jẹ alufaa ní àwọn ibi pẹpẹ ìrúbọ káàkiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin nkan yi, Jeroboamu kò pada kuro ninu ọ̀na ibi rẹ̀, ṣugbọn o tun mu ninu awọn enia ṣe alufa ibi giga wọnni: ẹnikẹni ti o ba fẹ, a yà a sọtọ̀ on a si di alufa ibi giga wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jéróbóámù kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí.