1 Kings 14:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ajá ni yóo jẹ òkú ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú; ẹni tí ó bá sì kú sinu igbó, ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.” ’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹni Jeroboamu ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ: ati ẹniti o ba kú ni igbẹ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio jẹ: nitori Oluwa ti sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ajá yóò jẹ ẹni Jéróbóámù tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní ìgbẹ́ ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. OLÚWA ti sọ ọ́!’