1 Kings 14:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọn yóo sì sin ín, nítorí òun nìkan ni wọ́n óo sin ninu ìdílé Jeroboamu, nítorí òun nìkan ni inú OLUWA Ọlọrun Israẹli dùn sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo Israeli yio si ṣọ̀fọ rẹ̀, nwọn o si sin i; nitori kiki on nikan li ẹniti yio wá si isa-okú ninu ẹniti iṣe ti Jeroboamu, nitori lọdọ rẹ̀ li a ri ohun rere diẹ sipa Oluwa, Ọlọrun Israeli, ni ile Jeroboamu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jéróbóámù, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ilé Jéróbóámù.