1 Kings 14:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà, wọn óo sì máa gbọ̀n bí ewé ojú omi. OLUWA yóo fà wọ́n tu kúrò ninu ilẹ̀ dáradára tí ó fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì fọ́n wọn káàkiri òdìkejì odò Yufurate, nítorí ère oriṣa Aṣerimu tí wọ́n ṣe tí ó mú OLUWA bínú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti Oluwa yio kọlu Israeli bi a ti imì iye ninu omi, yio si fa Israeli tu kuro ni ilẹ rere yi, ti o ti fi fun awọn baba wọn, yio si fọ́n wọn ka kọja odò na, nitoriti nwọn ṣe ere oriṣa wọn, nwọn si nru ibinu Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò kọlu Ísírẹ́lì, yóò sì dà bí a ti ń mi ìyẹ́ nínú omi. Yóò sì fa Ísírẹ́lì tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò, nítorí wọ́n ti rú ìbínú OLÚWA nípa ṣíṣe ère òrìṣà.