1 Kings 14:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jeroboamu ọba ṣe: àwọn ogun tí ó jà, ati bí ó ti ṣe ṣe ìjọba rẹ̀, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé àkọsílẹ̀ Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iyokù iṣe Jeroboamu, bi o ti jagun, ati bi o ti jọba, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyòókù ìṣe Jéróbóámù, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì.