1 Kings 14:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jeroboamu wí fún aya rẹ̀ pé, “Dìde, kí o yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má lè dá ọ mọ̀ pé aya ọba ni ọ́. Lọ sí Ṣilo níbi tí wolii Ahija tí ó wí fún mi pé n óo jọba Israẹli, ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jeroboamu si wi fun aya rẹ̀ pe, Dide, emi bẹ̀ ọ, si pa ara rẹ dà, ki a má ba le mọ̀ ọ li aya Jeroboamu; ki o si lọ si Ṣilo: kiyesi i, nibẹ li Ahijah, woli wà, ti o sọ fun mi pe, emi o jọba lori enia yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéróbóámù sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́ ní aya Jéróbóámù. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣílò. Áhíjà wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jọba lórí àwọn ènìyàn yìí.