1 Kings 14:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni ọdún mọkanlelogoji ni Rehoboamu ọmọ Solomoni nígbà tí ó gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda, ọdún mẹtadinlogun ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin gbogbo ilẹ̀ Israẹli fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ̀. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Rehoboamu, ọmọ Solomoni, si jọba ni Juda: Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanlelogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Réhóbóámù ọmọ Sólómónì sì jọba ní Júdà. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó sì jọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí OLÚWA ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà, ará Ámónì.