1 Kings 14:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin tí wọ́n sọ ara wọn di aṣẹ́wó ní ojúbọ àwọn oriṣa náà sì pọ̀ ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe, ni àwọn náà ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti nhùwa panṣaga mbẹ ni ilẹ na: nwọn si ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun irira awọn orilẹ-ède ti Oluwa lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí ń hùwà panṣágà sì tún ń bẹ ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí OLÚWA ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.