1 Kings 14:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Aya Jeroboamu sì ṣe bí Jeroboamu ti wí. Ó lọ sí ilé wolii Ahija ní Ṣilo. Ogbó ti dé sí Ahija ní àkókò yìí, kò sì ríran mọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aya Jeroboamu si ṣe bẹ̃, o si dide, o si lọ si Ṣilo, o si wá si ile Ahijah. Ṣugbọn Ahijah kò riran; nitoriti oju rẹ̀ fọ́ nitori ogbó rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni aya Jéróbóámù sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Áhíjà ní Ṣílò. Áhíjà kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀.