1 Kings 14:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn OLUWA ti sọ fún un pé aya Jeroboamu ń bọ̀ wá bèèrè ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ń ṣàìsàn, OLUWA sì ti sọ ohun tí Ahija yóo sọ fún un. Nígbà tí aya Jeroboamu dé, ó ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun Ahijah, pe, Kiyesi i, aya Jeroboamu mbọ̀ wá bère ohun kan lọwọ rẹ niti ọmọ rẹ̀: nitori ti o ṣàisan: bayi bayi ni ki iwọ ki o wi fun u: yio si ṣe, nigbati o ba wọle, yio ṣe ara rẹ̀ bi ẹlomiran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n OLÚWA ti sọ fún Áhíjà pé, “Kíyèsí i, aya Jéróbóámù ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”