1 Kings 14:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí Ahija ti gbúròó rẹ̀ tí ó ń wọlé bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wọlé, ìwọ aya Jeroboamu. Kí ló dé tí o fi ń ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni ọ́? Ìròyìn burúkú ni mo ní fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ li o si ri, nigbati Ahijah gbọ́ iró ẹsẹ rẹ̀, bi o ti mbọ̀ wá li ẹnu ọ̀na, on si wipe, Wọle wá, iwọ, aya Jeroboamu, ẽṣe ti iwọ fi ṣe ara rẹ bi ẹlomiran? nitori iṣẹ wuwo li a fi rán mi si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Áhíjà sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jéróbóámù. Kíló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ.