1 Kings 14:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo gba ìjọba lọ́wọ́ ìdílé Dafidi, mo sì fún ọ, o kò ṣe bíi Dafidi, iranṣẹ mi, tí ó pa òfin mi mọ́, tí ó sìn mí tọkàntọkàn, tí ó sì ṣe kìkì ohun tí ó dára lójú mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti mo si fà ijọba ya kuro ni ile Dafidi, mo si fi i fun ọ: sibẹ iwọ kò ri bi Dafidi iranṣẹ mi, ẹniti o pa ofin mi mọ, ti o si tọ̀ mi lẹhin tọkàntọkàn rẹ̀, lati ṣe kiki eyi ti o tọ li oju mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, iwọ kò dàbí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi.