1 Kings 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn o ti dá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ju ti àwọn tí wọ́n jọba ṣáájú rẹ lọ. O yá ère, o sì dá oniruuru oriṣa láti máa sìn, o mú mi bínú, o sì ti pada lẹ́yìn mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ ti ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o ti wà ṣaju rẹ: nitori iwọ ti lọ, iwọ si ti ṣe awọn ọlọrun miran, ati ere didà, lati ru ibinu mi, ti iwọ si ti gbé mi sọ si ẹhin rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn Ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbémi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.