1 Kings 15:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó yọ Maaka, ìyá baba rẹ̀, kúrò lórí oyè ìyá ọba, nítorí pé Maaka yá ère tí ó tini lójú kan fún oriṣa Aṣera. Asa gé oriṣa náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún ní àfonífojì Kidironi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì mú Máákà ìyá ìyá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún òrìṣà rẹ̀. Áṣà sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún níbi odò Kídírónì.