1 Kings 15:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Asa ọba bá kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó kù ninu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA ati ti ààfin ọba jọ, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ sí Benhadadi ọmọ Tabirimoni, ọmọ Hesioni, ọba ilẹ̀ Siria, tí ó wà ní ìlú Damasku. Asa ní kí wọ́n wí fún Benhadadi,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Áṣà mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé OLÚWA àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Bẹni-Hádádì ọmọ Tábírímónì, ọmọ Hésíónì ọba Síríà tí ó ń gbé ní Dámásíkù.