1 Kings 15:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
pé, “Jẹ́ kí a ní àjọṣepọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe; gba wúrà ati fadaka tí mo fi ranṣẹ sí ọ yìí, kí o dẹ́kun àjọṣepọ̀ rẹ pẹlu Baaṣa ọba Israẹli, kí ó lè kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrin èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrin bàbá mi àti bàbá rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”