1 Kings 15:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Benhadadi ọba gba ohun tí Asa wí, ó sì rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ láti lọ gbógun ti àwọn ìlú ńláńlá Israẹli. Wọ́n gba ìlú Ijoni ati Dani, Abeli Beti Maaka, ati gbogbo agbègbè Kineroti, pẹlu gbogbo agbègbè Nafutali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹni-Hádádì gba ti Áṣà ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì. Ó sì ṣẹ́gun Íjónì, Dánì àti Abeli-Bẹti-Máákà, àti gbogbo Kénérótì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náfútalì.