1 Kings 15:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹsẹkẹsẹ tí Baaṣa gorí oyè ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìdílé Jeroboamu. Gbogbo ìran Jeroboamu pátá ni Baaṣa pa láìku ẹyọ ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu iranṣẹ rẹ̀, wolii Ahija, ará Ṣilo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati o jọba, o kọlu gbogbo ile Jeroboamu; kò kù fun Jeroboamu ẹniti nmí, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Ọluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah ara Ṣilo:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ó pa gbogbo ilé Jéróbóámù, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jéróbóámù, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA, tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Áhíjà ará Ṣílò: