1 Kings 15:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọdún kẹta tí Asa, ọba Juda, gorí oyè, ni Baaṣa, ọmọ Ahija, gorí oyè, ní ìlú Tirisa, ó sì di ọba gbogbo Israẹli. Ó jọba fún ọdún mẹrinlelogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun kẹta Asa, ọba Juda, ni Baaṣa, ọmọ Ahijah bẹ̀rẹ si ijọba lori gbogbo Israeli ni Tirsa, li ọdun mẹrinlelogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, Bááṣà ọmọ Áhíjà sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà, ó sì jọba ní ọdún mẹ́rìnlélógún.