1 Kings 15:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sibẹsibẹ, nítorí ti Dafidi, OLUWA Ọlọrun fún Abijamu ní ọmọkunrin kan tí ó gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ní Jerusalẹmu, tí ó sì dáàbò bo Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, nítorí i Dáfídì OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jérúsálẹ́mù nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀.