1 Kings 15:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí rẹ̀ ni pé, Dafidi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, kò sì ṣàìgbọràn sí àṣẹ rẹ̀ rí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, (àfi ohun tí ó ṣe sí Uraya ará Hiti).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí Dáfídì ṣe èyí tí ó dára ní ojú OLÚWA, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí OLÚWA pa láṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Ùráyà ará Hítì.