1 Kings 16:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Simiri ti gorí oyè, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba ni ó pa gbogbo àwọn ìdílé Baaṣa patapata. Gbogbo àwọn ìbátan ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọkunrin ni ó pa láìdá ẹnikẹ́ni sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Bááṣà pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́.