1 Kings 16:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, Simiri gorí oyè ní Tirisa, ó sì jọba Israẹli fún ọjọ́ meje. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ogun Israẹli gbógun ti ìlú Gibetoni ní ilẹ̀ Filistia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Simri jọba ijọ meje ni Tirsa. Awọn enia si do tì Gibbetoni, ti awọn ara Filistia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, ni Ṣímírì jọba ọjọ́ méje ní Tírísà. Àwọn ọmọ ogun sì dó ti Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì.