1 Kings 16:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹni pé, gbogbo àìdára tí Ahabu ọba ṣe bíi ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, kò burú tó, ó tún lọ fẹ́ Jesebẹli ọmọbinrin Etibaali, ọba Sidoni, ó sì ń bọ oriṣa Baali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, ó sì mú Jésébélì, ọmọbìnrin Étíbáálì, ọba àwọn ará Sídónì ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Báálì, ó sì bọ ọ́.