1 Kings 16:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò ìgbà tirẹ̀ ni Hieli ará Bẹtẹli tún ìlú Jẹriko kọ́. Abiramu àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin kú, nígbà tí Hieli fi ìpìlẹ̀ ìlú Jẹriko lélẹ̀. Segubu, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ọkunrin sì tún kú bákan náà, nígbà tí ó gbé ìlẹ̀kùn sí ẹnubodè rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu Joṣua, ọmọ Nuni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ rẹ̀ ni Hieli, ara Beteli, kọ́ Jeriko: o fi ipilẹ rẹ̀ le ilẹ ni Abiramu, akọbi rẹ̀, o si gbé awọn ilẹkun ibode rẹ̀ kọ́ ni Segubu abikẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Joṣua, ọmọ Nuni sọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà ayé Áhábù, Híélì ará Bétélì kọ́ Jẹ́ríkò. Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Ábírámù, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Ṣégúdù àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti ipa Jóṣúà ọmọ Núnì sọ.