1 Kings 16:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà OLUWA ti ẹnu wolii Jehu ọmọ Hanani bá Baaṣa ati ìdílé rẹ̀ wí nítorí gbogbo ibi tí ó ṣe lójú OLUWA, tí ó fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mú OLUWA bínú nítorí pé ó dẹ́ṣẹ̀ bíi Jeroboamu, ati pé òun ló tún pa ìdílé Jeroboamu run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì wá nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì ọmọ Hánánì pẹ̀lú sí Bááṣà àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo búburú tí ó ti ṣe níwájú OLÚWA, ní mímú un bínú nípa ohun tó ti ṣe àti wíwà bí ilé Jéróbóámù: àti nítorí tí ó pa á run pẹ̀lú.