1 Kings 17:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wolii kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elija, ará Tiṣibe, ní Gileadi, sọ fún Ahabu pé, “Bí OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí mò ń sìn ti wà láàyè, mò ń sọ fún ọ pé, òjò kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìrì kò ní sẹ̀ fún ọdún mélòó kan, àfi ìgbà tí mo bá sọ pé, kí òjò rọ̀, tabi kí ìrì sẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ELIJAH ara Tiṣbi, lati inu awọn olugbe Gileadi, wi fun Ahabu pe, Bi Oluwa Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọ̀rọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíjà ará Tíṣíbì, láti Tíṣíbì ní Gílíádì wí fún Áhábù pé, “Bí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”