1 Kings 17:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Elija bá lọ sí Sarefati. Bí ó ti dé ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà, ó rí obinrin opó kan tí ń wá igi ìdáná. Ó wí fún obinrin yìí pé, “Jọ̀wọ́ lọ bá mi bu omi wá kí n mu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Ṣáréfátì. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”