1 Kings 17:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Elija wí fún un pé, “Má bẹ̀rù. Lọ se oúnjẹ tí o fẹ́ sè, ṣugbọn kọ́kọ́ tọ́jú díẹ̀ lára rẹ̀, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, kí o lọ sè fún ara rẹ ati fún ọmọ rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elijah si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; lọ, ki o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi; ṣugbọn ki o tètekọ ṣe àkara kekere kan fun mi ninu rẹ̀ na, ki o si mu u fun mi wá, lẹhin na, ki o ṣe tirẹ ati ti ọmọ rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíjà sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ.