1 Kings 17:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli wí ni pé, ìyẹ̀fun kò ní tán ninu ìkòkò rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ kò ní gbẹ títí tí OLUWA yóo fi rọ òjò sórí ilẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: Ikoko iyẹfun na kì yio ṣòfo, bẹni kólobo ororo na kì yio gbẹ, titi di ọjọ ti Oluwa yio rọ̀ òjo si ori ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí OLÚWA yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”