1 Kings 18:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, kò si orilẹ-ède tabi ijọba kan, nibiti oluwa mi kò ranṣẹ de lati wò ọ: nigbati nwọn ba si wipe, Kò si; on a mu ki ijọba tabi orilẹ-ède na bura pe: awọn kò ri ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo mọ̀ dájú pé bí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.