1 Kings 18:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe bi emi o ti lọ kuro li ọdọ rẹ, Ẹmi Oluwa yio si gbe ọ lọ si ibi ti emi kò mọ̀; nigbati mo ba si de, ti mo si wi fun Ahabu, ti kò ba si ri ọ, on o pa mi: ṣugbọn emi, iranṣẹ rẹ, bẹ̀ru Oluwa lati igba ewe mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí OLÚWA yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀. Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Áhábù, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí. Ṣíbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù OLÚWA láti ìgbà èwe mi wá.