1 Kings 18:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elijah si wi fun awọn enia na pe, Emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù ni woli Oluwa; ṣugbọn awọn woli Baali ãdọta-lenirinwo ọkunrin,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Èlíjà wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì OLÚWA, ṣùgbọ́n, àádọ́tàlénírinwó (450) ni wòlíì Báálì.