1 Kings 18:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina jẹ ki nwọn ki o fun wa li ẹgbọrọ akọ-malu meji; ki nwọn ki o si yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara wọn, ki nwọn ki o si ke e, ki nwọn ki o si tò o si ori igi, ki nwọn ki o má ṣe fi iná si i: emi o si tun ẹgbọrọ akọ-malu keji ṣe, emi o si tò o sori igi, emi kì o si fi iná si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ fún wa ní ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì ké e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.