1 Kings 18:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elijah si wi fun awọn woli Baali pe, Ẹ yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara nyin, ki ẹ si tètekọ ṣe e: nitori ẹnyin pọ̀: ki ẹ si kepè orukọ awọn ọlọrun nyin, ṣugbọn ẹ máṣe fi iná si i,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíjà sì wí fún àwọn wòlíì Báálì wí pé, “Ẹ yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.”