1 Kings 18:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati ọjọ kan atarí, nwọn si nfi were sọtẹlẹ titi di akoko irubọ aṣalẹ, kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn, tabi ẹniti o kà a si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì sí ìdáhùn, kò sì sí ẹni tí ó kà á sí.