1 Kings 18:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ Elijah wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹ sunmọ mi. Gbogbo awọn enia na si sunmọ ọ. On si tun pẹpẹ Oluwa ti o ti wo lulẹ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Èlíjà wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi.” Wọ́n sì sún mọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ OLÚWA tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe.