1 Kings 18:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si to igi na daradara, o si ke ẹgbọrọ akọ-malu na, o si tò o sori igi, o si wipe, fi omi kún ikoko mẹrin, ki ẹ si tú u sori ẹbọ sisun ati sori igi na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi. Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, “Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tun sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà.”