1 Kings 18:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣáálẹ́, wòlíì Èlíjà sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “OLÚWA, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.