1 Kings 18:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá sọ iná sílẹ̀, iná náà sì jó ẹbọ náà ati igi, ati òkúta. Ó jó gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó sì lá gbogbo omi tí ó wà ninu kòtò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni iná Oluwa bọ́ silẹ, o si sun ẹbọsisun na ati igi, ati okuta wọnnì, ati erupẹ o si lá omi ti mbẹ ninu yàra na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni iná OLÚWA bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ síṣun náà àti igi, àti àwọn Òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrà náà.