1 Kings 18:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jesebẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn wolii OLUWA, Ọbadaya yìí ló kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, ó kó aadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jésébélì sì ń pa àwọn wòlíì OLÚWA kúrò, Ọbadíà sì mú ọgọ́rùn ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.