1 Kings 18:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Elija bá pàṣẹ pé, “Ẹ mú gbogbo àwọn wolii oriṣa Baali! Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wọn sá lọ.” Àwọn eniyan náà bá ki gbogbo wọn mọ́lẹ̀, Elija kó wọn lọ sí ibi odò Kiṣoni, ó sì pa wọ́n sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elijah si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn woli Baali; máṣe jẹ ki ọkan ninu wọn ki o salà. Nwọn si mu wọn: Elijah si mu wọn sọkalẹ si odò Kiṣoni, o si pa wọn nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Èlíjà sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn wòlíì Báálì. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sá lọ!” Wọ́n sì mú wọn, Èlíjà sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí odò Kíṣónì, ó sì pa wọ́n níbẹ̀.