1 Kings 18:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.” Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọ̀sánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.” Èlíjà sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ”