1 Kings 18:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láìpẹ́, ìkùukùu bo gbogbo ojú ọ̀run, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, òjò ńlá sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ahabu kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì pada lọ sí Jesireeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigba diẹ si i, ọrun si ṣu fun awọsanmọ on iji, òjo pupọ si rọ̀. Ahabu si gun kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì sú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Áhábù sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jésírẹ́lì.