1 Kings 19:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliṣa fi àjàgà mààlúù rẹ̀ sílẹ̀, ó sáré tẹ̀lé Elija, o wí fún un pé, “Jẹ́ kí n lọ dágbére fún baba ati ìyá mi, kí n fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, kí n tó máa tẹ̀lé ọ.” Elija dá a lóhùn pé, “Pada lọ, àbí, kí ni mo ṣe fún ọ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Èlíṣà sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì ṣáré tọ Èlíjà lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Èlíjà sì dáhùn wí pé, “Padà ṣẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?”