1 Kings 19:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eliṣa bá pada lẹ́yìn rẹ̀ sí ibi tí àwọn akọ mààlúù rẹ̀ wà, ó pa wọ́n. Ó fi igi tí ó fi ṣe àjàgà wọn ṣe igi ìdáná, ó bá se ẹran wọn. Ó pín ẹran náà fún àwọn eniyan, wọ́n sì jẹ ẹ́. Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Elija, ó ń tẹ̀lé e, ó sì ń ṣe iranṣẹ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà sì fi í sílẹ̀, ó padà ṣẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun-èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Èlíjà lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.