1 Kings 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Ísírẹ́lì ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ OLÚWA wá.