1 Kings 2:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Bátíṣébà sì tọ Sólómónì ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Àdóníjà, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.