1 Kings 2:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún Ábíátarì àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Ánátótì, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsìn yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA níwájú Dáfídì baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.”